Wednesday, June 25, 2014

Opuro Orebirin f'iku Se Ifa Je


Leyin opolopo ojo ti won ti n wa eni ti o pa arabinrin Cicely Bolden , eni odun mejidinlogbon (28), oko afesona re ma ti jade si gbangba pe oun loun ran arabinrin naa si orun are mo bo , ogbeni Larry Dunn omo ilu Dallas Texas eni odun merindinlogoji (36) lo jewo ni gbangba walia pe oun loun pa Cicely nitori pe o paro fun oun pe oun ko ni kokoro arun HIV sugbon leyin osu die ti awon ti n sere ife lo to jewo sugbon leyin ayewo ni kokoro naa fara han ninu eje oun naa.


Femi

Tuesday, June 24, 2014

OSIKA EDA. Owo ti te e o

Owo ti te e o , ani owo ma ti te e,owo ti te osika eda yen ti o pa omo bibi inu ara re nitori iresi (rice) agolo kan pere.Kingsley Ekerete, eni odun mokandinlogbon (29 years) omo bibi ipinle Akwam Ibon lo sa deede fun omobinrin omo bibi inu ara re lorun pa nitori agolo rice kan , omo odun meje pere ni omobinrin naa ti Kingsley fun lorun pa ti o si gbe oku omo naa lo sinu igbo ti o si sin omo naa sibe , sugbon leyin ojo keta eje omo naa ke fun esan lori baba re,owo awon olopa ipinle Rivers ti te e

Femi

Sunday, June 15, 2014

KINI KI A PE EYI O !!! Se efun ni ki a pe e ni tabi eedi

 Sa deede ni awon kokoro oyin igan (bees) bi egberun lona ogun (20,000) bo arabinrin ti o n koja niwaju ile itaja nla kan ni opopona Victoria ni ilu London bi o tile je pe enikeni ko mo oruko omobinrin naa ti awon oyin naa si ta a titi o fi ku sibe. Ninu iwadi ti a se won ni o seese ki o je pe obinrin naa lo awon lofinda oloorun didun lo fa a ti awon kokoro oyin naa se toro mo-on. A ro eyin ti e n lo lofinda oloorun didun ki e sora ooooo

OWO TI TE WON O !!! Owo te Meta ninu awon omo iko gbemi gbemi Boko Haram ni ojo eti


 
Meta ninu awon omo iko gbemi gbemi Boko Haram ti won pa opolopo eniyan laipe yi ni Ijoba Ibile Gwoza ni iko JTF ti te ni ijeta ojo eti , enikan ti awon iko naa du egbon re bi eni du eran lo da okan mo ninu keke Maruwa ti won jo wo , oju ese ni o figbe ta pe oun mo okunrin ti o joko ti oun gege bi okan ninu awon omo iko Boko Haram nigba ti owo iya ba a daadaa lohun naa ba naka si awon meji miran pe ara kan ni awon , loju ese ni won si fa won le olopa lowo .

Femi

Sunday, June 1, 2014

Ohun Buruku Ni Ko Taka Sori

Nibi ti omo Yoruba bawa, tI aba ri eni so oro buruku tabi oro odi, awon omo Yoruba ti oba wa ni be ma taka l'emeta ni kiakia, won a tuni 'Olorun maje'. Iye tumosi pe, oro buruku yen ti fowo n da.
Ohun lodifa fun mama Ajala to ntata ni ita katakara. Tiwon soro odi legbe e, ti ko tete taka danu, atanpako e di talantolo, lojo keji, o gbo ohun eye Ibaka to nso 'Ohun buruku ni ko taka sori' Mama Ajala yara fi ata re sile o lo fo ori e nu ni odo to nso legbe ile Alara to nta taba loja Afariga. Won bi mama Ajala lere wipe kilode to nfi fori nu, o nihun ti eye ri ti ofi ni kohun taka, nigba tohun o teteri eni tasi, lohun ya lo fori nu s'odo to nso.
Nitori idi eyi, e maje ki won taka le yin lori o
"E ya yara taka osi danu"

ST