Thursday, July 31, 2014

KABIYESI OLORUN: Ibrahim pade omobinrin arewa kan ti oruko re n je Ameena


. Ase otito ni oro awon agba ti won so pe "Olodumare ko gbagbe enikankan"be e gege ni oro Arif Ibrahim Tambe eni ti ko ga ju ese bata kan abo lo se ri. Laipe yi ni Ibrahim pade omobinrin arewa kan ti oruko re n je Ameena Ahmed eni odun mokanlelogun. Loju ese ti omobinrin yi ri arakunrin yi ni ife rado bo o mole , loju ese lo si konu ife si Ibrahim pe oun fe fe e , o ni ki I wa se fife nikan , oun yo fi se oko ti oun yo maa bimo fun un. Oro yi jo Ibrahim loju lojo naa tori n se ni awon obinrin ma n fi I se yeye.Ibrahim so fun Ameena pe ti yo ba fe oun , ohun ni yoo ma se gbogbo ise ile o , yo ma we oun , yo maa ba oun fo aso , yo si maa gbe igbe oun danu bi ti omode , arabinrin naa si gba be e. Ni bayi Ibrahim pelu Ameena ti di t'oko t'aya o koda Olorun ti fi omo ta won lore , awon mejeeji si n gbe igbe alafia ni iwo oorun India (West of India). Huumm , a se ko si oun ti Olorun ko le se.

Femi.

Wednesday, July 30, 2014

O MA SE O !!! El-Rufai padanu okan ninu awon omokunrin re

Oro yi lo n jade lenu awon ti won sun mon eni ti o ti fi igba kan je Minista Abuja tele , Malam Nasir El-Rufai eni ti o padanu okan ninu awon omokunrin re laaro yi , Hamza El-Rufai ni oruko omokunrin naa n je , eni ti o ku ninu ijamba moto kan ti o sele laaro yi , ORO TO N LO gba a ni adura ki Olorun ba wa tu ebi naa ninu. Ti e ko ba gbagbe ni osu die seyin ni idile yi kan naa padanu omobinrin awelewa kan. A gba ni adura ki Olorun ninu aanu re dawo isele ibi duro lori idile naa.

Femi 

Monday, July 28, 2014

KIN LO DE ? Isele Ni deedee agogo meji osan

 Ni deedee agogo meji osan yi ni Obinrin kan sa deedee yo sibi ti awon olopa ti n seeto lati ko awon oku ti bombu pa laaro yi kuro nile ni ile Epo nla Hotoro ni ilu Kano. Bi obinrin eleha naa se de agbegbe naa ni awon agbofinro ti o wa nibe ti n fura si I , loju ese lo ba mori le ona ibudo ipate oja (Kano Trade fair Complex) nibi ti Ogunlogo awon olopa wa , ninu akiyesi awon olopa , won ri pe ara Obinrin naa ko bale ati pe o ro kini kan mo aso ibori re ti awon Musulumi n pe ni Hijab , loju ese ni awon Olopa ba sun mo on , nibi ti won ti n fi oro wa a lenu wo ni ado oloro (bomb) ti o gbe sara ti dun lojiji ti o si ja obinrin naa jaka jaka , bakan naa lo se awon Olopa merin ti o sunmo on lese lopolopo. E jowo e ma dake adura ooo , ti e ko ba gbagbe obinrin kan ti koko ju bombu sile epo Hotoro ni Kano laaro yi .

Sunday, July 27, 2014

KIN LO DE ? Ibeere yi ni awon olugbe ipinle Osun n beere lowo ara won

Ni pataki awon olugbe ilu Ilesa nibi ti awon ololufe egbe APC ati PDP ti fija peeta lori ibo ti n bo lona , ti eniyan meji si gbemi min ti opolopo si fi ara pa.Ibeere ti o wa n tawo tase ninu awon eniyan ni pe kin lo le fa ija ajaku akata yi lori pe a fe sin awon eniyan.E jowo gbogbo eyin Ori Ade ati eyin ejigbara Orun ileke,e bawa da awon onijongbon yi lowo ko o,a ko fe ogun ni Ipinle Osun oooo

Femi

Friday, July 25, 2014

Lo ba tan, OWO TE OSIKA EDA !!!



Owo ma ti te e o , ni aye ijohun ni a maa n so pe awon obinrin ni oju aanu sugbon bayi,Opolopo won ni won daju ju ile agba lo. Ti e ko ba gbagbe ni ose die seyin la foju awon obinrin meta ti owo te pe won n ba awon iko Boko Haram sise po han lori eto yi,ase kekere la ri nigba naa,ni ijeta ojo'ru ni Obinrin miran tun ju ado Oloro nibi ti Dahiru Bauchi ti n se waasi , ori lo yo baba naa ti ko ba isele naa lo ni ilu Kaduna, Obinrin yi kaa naa lo tun saaju iko gbemi gbemi ti won tun kolu olori orile ede yi nigba kan ri , Ogagun Mohammadu Buhari ni ireti ati gbemi okunrin naa , sugbon ori ko ohun naa yo , abalo ababo ninu isele mejeeji ti obinrin yi ti ju bombu lojo naa lo ti ran Ogoji eniyan si orun apapa n dodo ti eniyan metadinlogosi si fara pa koja ala . Haaaaaa , Obinrin n gbase bombu jiju , awon naa ti n gbemi alaise .

Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.


Ẹyin ara wa tootọ,
Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.
Ibeere tení ní:
"ṣe o ba aṣa Yoruba mu kí obínrín kọ ẹnu ífẹ sí ọkunrín ??"
Ẹyín ọjọgbọn, ẹ ba wa da sí

Tuesday, July 22, 2014

Igbeyawo ara oto ti o sele ni Orile Ede



 Huuummm, bi aye ba n lo si opin orisirisi nkan ti ko sele ri ni yoo ma waye , iru re ni eyi ti o sele ni Orile Ede South Africa laipe yi nibi ti omokunrin omo odun Mesan (9) ti se igbeyawo alarinrin pelu iya agbalagba eni odun mejilelogota (62) Igbeyawo naa dun o si larinrin , sugbon emi o mo oun ti won fe fayo ninu iru igbeyawo bee. Ti e ba fe darapo mo ORO TO N LO ni ori Whatsapp nibi ti a ti n so ede Oyinbo e dara po mo wa pelu nomba yi 08034032049.

Femi

OBI RERE: Chein duro pelu baba re ninu aso oye re



. Ojogbon Chein joi ni e n wo ninu aso oye re yi , leyin opolopo wahala ati ila hilo , Omo pandoro re ma ti gbo o , Chein lo duro pelu baba re yi ninu aso oye re leyin ti o pari eko re ni Yunifasiti Orile ede China . Baba yi lo ta oun gbogbo ti o ni lati ri pe omo oun kawe gboye ni Yunifasiti. A dupe pe omo naa ti gboye bayi , e wo aso ti o wa lorun baba lojo eye omo re nitori pe ko ni aso miran , melo ninu awon obi lo le se eleyi , e jeki awa obi toju awon omo wa o. Whatsapp 08034032049.

Thursday, July 17, 2014

Se Oro Yi Ko Ti l'owo Kan Oselu Ninu Bayi ?

Huum , nje oro to wa nile yi ko ti ni owo kan oselu ninu bayi , ha, Oro awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko Haram ji ko pamo mo ni ooo , ni ojo isegun ijeta ni Aare Goodluck Ebele Jonathan pe awon obi awon omo wonyi ati marun ninu awon omo ti won ti jaja bo lowo iko gbemi gbemi Boko Haram naa si ipade , sugbon ti okankan ninu awon obi naa ko yoju si ipade naa ni ilu Abuja , eyi lo wa mu ki ara maa fu ORO TO N LO pe , Se oro yi ko ti l'owo kan oselu ninu bayi ?

Femi Ojewale

Wednesday, July 16, 2014

Eyin eniyan mi ebami fun ogbeni yi ni oruko


Tuesday, July 15, 2014

IRU IWA WO NIYI. Gbogbo eyin eeyan mi ?

 Eyin omo Yoruba atata , iru iwa idojuti wo niyi ni gbangba walia , ki obinrin maa ja ija ajadiju nitori oro okunrin , huuummmm , se o dara beeeeee

Oruko Kan Fun Ogbeni Yii !


Thursday, July 10, 2014

Idunmi ko ni di ibanuje Ase. iwo nko?


Igbekele mi ko ni ha si asan.
Ayo mi ko ni di Ibanuje.
Ase!

Wednesday, July 9, 2014

Fọto: Eyin temi tani o wu iwa odaju ika ninu awon meejeeji yi ooo


Eyin temi tani o wu iwa odaju ika ninu awon meejeeji yi ooo ?

Monday, July 7, 2014

ADURA WA SE PATAKI - Oro awon omobinrin ile iwe Chibok

. Mo tun ki yin , E ku ojumo ooo , Ojumo ayo lo ma mon gbogbo wa loni o (Amin Ase). Huuuummmm , e ma binu pe mo mi kanle lekan si I . Oro awon omobinrin ile iwe Chibok ti awon iko gbemi gbemi Boko Haram ko ni igbekun lati bi osu die seyin lo ma n ko mi lominu , die lara foto awon omo naa niyi o , mo wa n fi asiko yi ati ola inu osu ti a wa yi be eyin omo leyin Ifa, Kristi ati Musulumi lati bawa gbe oun adura soke ki awon omo yi pada wale layo ati alafia ............

Femi Ojewale

Sunday, July 6, 2014

HAA OBINRIN: owo te awon Obinrin meta Boko Haramu

............... Hummmm , ase eniyan ni ole , o ma se o, ibanuje nla lo je fun mi nigba ti mo gbo pe owo te awon Obinrin meta ninu awon obinrin ti won n se alami fun iko Boko Haram ni ijeta. Haaaaaa , Obinrin ti o mo wahala ti awon n se lori iloyun , irobi , itoju omo ati itoju ile ti o wa tun je pe lara won ni won tun n se agbodegba fun iko gbemi gbemi , o ma se ooooo

Femi Ojewale

IWA AFOWOFA.

 E wo arabinrin yi ni a gbo pe o gbe Oogun oloro pamo sinu ikun re sugbon ti Oogun na be sinu arabinrin naa , ni o ba loyun Oogun oloro , se nitori owo yi naa , E dakun e jeki a sora ooooooo

Femi Ojewale

Itan Apẹrẹ ati Ikoko.


Ni aye atijọ Apẹrẹ ati Ikoko jẹ ọrẹ timotimo
koda o l'oju ẹni tole ri aarin wọn. L'ọjọ kan
ni Ikoko gbera o di ọdọ Apẹrẹ nigbati o de
bẹ wọn ki ara wọn gegebi ọrẹ atata, laipẹ
ni omoge awelewa kan nbọ ti osi da ede
ayede sile laarin wọn.

Thursday, July 3, 2014

Oruko kan fun arakunrin yi


Gbolohun kan fun awon okunrin yi losan awe


Oro kan fun ALHAJA YI


ST